The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Romans 6
Àti pé, kín ni ìyọrísí rẹ̀? Dájúdájú àbájáde rẹ̀ kò dára. Níwọ́n ìgbà tí ojú ń tì ọ́ nísinsin yìí láti ronú nípa àwọn wọ̀n-ọn-nì tí o ti máa ń ṣe nítorí gbogbo wọn yọrí sí ìparun ayérayé.
Romans 6:21 · Bíbélì Mímọ́
What fruit had ye then in those things whereof ye are now ashamed? for the end of those things is death.
What fruit did you reap at that time from the things of which you are now ashamed? The outcome of those things is death.
What fruit then did you have at that time in the things of which you are now ashamed? For the end of those things is death.
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
18 Nísinsin yìí, ẹ ti dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ọ̀gá yín àtijọ́, èyí tí í ṣe ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú ọ̀gá tuntun èyí ni òdodo.
19 Èmi ń sọ̀rọ̀ bí ènìyàn nítorí àìlera yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yín ti jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín lọ́wọ́ bí ẹrú fún ìwà èérí àti ẹ̀ṣẹ̀ dé inú ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí ẹ̀yin kí ó jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín lọ́wọ́ nísinsin yìí bí ẹrú fún òdodo sí ìwà mímọ́.
20 Nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin wà ní òmìnira sí òdodo.
21 Àti pé, kín ni ìyọrísí rẹ̀? Dájúdájú àbájáde rẹ̀ kò dára. Níwọ́n ìgbà tí ojú ń tì ọ́ nísinsin yìí láti ronú nípa àwọn wọ̀n-ọn-nì tí o ti máa ń ṣe nítorí gbogbo wọn yọrí sí ìparun ayérayé.
22 Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú Ọlọ́run àwọn ìbùkún rẹ̀ sí yin ni ìwà mímọ́ àti ìyè tí kò nípẹ̀kun.
23 Nítorí ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn Ọlọ́run ni ìyè àìnípẹ̀kun nínú Kristi Jesu Olúwa wa.
Read Romans 6 in the app The whole chapter