The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Mark 11
Bí wọ́n ti ń tú u, díẹ̀ nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀ bi wọ́n léèrè pé, “Ki ni ẹyin n ṣe, tí ẹ̀yin fi ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ n nì?”
Mark 11:5 · Bíbélì Mímọ́
And certain of them that stood there said unto them, What do ye, loosing the colt?
and some who were standing there asked, “Why are you untying the colt?”
Some of those who stood there asked them, “What are you doing, untying the young donkey?”
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
2 Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tó wà lọ́hùn ún nì. Nígbà tí ẹ bá sì wọlé, ẹ̀yin yóò rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí a so mọ́lẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ì tí i gùn rí. Ẹ tú u, kí ẹ sì mú wá sí ibi yìí.
3 Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe èyí?’ Ẹ sọ fún un pé, ‘Olúwa ní í fi ṣe, yóò sì dá a padà síbí láìpẹ́.’ ”
4 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà lọ bí ó ti rán wọn. Wọ́n rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tí a so ní ẹnu-ọ̀nà lóde ní ìta gbangba, wọ́n sì tú u.
5 Bí wọ́n ti ń tú u, díẹ̀ nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀ bi wọ́n léèrè pé, “Ki ni ẹyin n ṣe, tí ẹ̀yin fi ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ n nì?”
6 Wọ́n sì wí fún wọn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ní kí wọ́n sọ, wọ́n sì jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ lọ.
7 Wọ́n fa ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tọ Jesu wá. Wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí ẹ̀yìn rẹ̀, òun sì jókòó lórí rẹ̀.
8 Àwọn púpọ̀ tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà. Àwọn mìíràn ṣẹ́ ẹ̀ka igi, wọ́n sì fọ́n wọn sí ọ̀nà.
Read Mark 11 in the app The whole chapter