The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Mark 11
Wọ́n sì wí fún wọn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ní kí wọ́n sọ, wọ́n sì jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ lọ.
Mark 11:6 · Bíbélì Mímọ́
And they said unto them even as Jesus had commanded: and they let them go.
The disciples answered as Jesus had instructed them, and the people gave them permission.
They said to them just as Jesus had said, and they let them go.
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
3 Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe èyí?’ Ẹ sọ fún un pé, ‘Olúwa ní í fi ṣe, yóò sì dá a padà síbí láìpẹ́.’ ”
4 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà lọ bí ó ti rán wọn. Wọ́n rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tí a so ní ẹnu-ọ̀nà lóde ní ìta gbangba, wọ́n sì tú u.
5 Bí wọ́n ti ń tú u, díẹ̀ nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀ bi wọ́n léèrè pé, “Ki ni ẹyin n ṣe, tí ẹ̀yin fi ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ n nì?”
6 Wọ́n sì wí fún wọn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ní kí wọ́n sọ, wọ́n sì jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ lọ.
7 Wọ́n fa ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tọ Jesu wá. Wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí ẹ̀yìn rẹ̀, òun sì jókòó lórí rẹ̀.
8 Àwọn púpọ̀ tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà. Àwọn mìíràn ṣẹ́ ẹ̀ka igi, wọ́n sì fọ́n wọn sí ọ̀nà.
9 Àti àwọn tí ń lọ níwájú, àti àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn, gbogbo wọn sì ń kígbe wí pé, “Hosana!” “Olùbùkún ni ẹni náà tí ó ń bọ̀ wà ní orúkọ Olúwa!”
Read Mark 11 in the app The whole chapter