The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Matthew 21

Matthew 21:16

Wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ ìwọ gbọ́ nǹkan tí àwọn ọmọdé wọ̀nyí ń sọ?” Jesu sí dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àbí ẹ̀yin kò kà á pé, “ ‘Láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ ọmú, ni a ó ti máa yìn mí’?”

Matthew 21:16 · Bíbélì Mímọ́

← PreviousRead Matthew 21Next →

Matthew 21:16 in other translations

KJV King James Version

And said unto him, Hearest thou what these say? And Jesus saith unto them, Yea; have ye never read, Out of the mouth of babes and sucklings thou hast perfected praise?

BSB Berean Standard Bible

“Do you hear what these children are saying?” they asked. “Yes,” Jesus answered. “Have you never read: ‘From the mouths of children and infants You have ordained praise’?”

WEB World English Bible

and said to him, “Do you hear what these are saying?” Jesus said to them, “Yes. Did you never read, ‘Out of the mouth of children and nursing babies, you have perfected praise’?”

Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.

In context

13 Ó wí fún wọn pé, “A sá à ti kọ ọ́ pé, ‘Ilé àdúrà ni a ó máa pe ilé mi,’ ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùdó àwọn ọlọ́ṣà.”

14 A sì mú àwọn afọ́jú àti àwọn arọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní tẹmpili, ó sì mú wọ́n láradá.

15 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin rí àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá wọ̀nyí, ti wọ́n sì tún ń gbọ́ tí àwọn ọmọdé ń kígbe nínú tẹmpili pé, “Hosana fún ọmọ Dafidi,” inú bí wọn.

16 Wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ ìwọ gbọ́ nǹkan tí àwọn ọmọdé wọ̀nyí ń sọ?” Jesu sí dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àbí ẹ̀yin kò kà á pé, “ ‘Láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ ọmú, ni a ó ti máa yìn mí’?”

17 Ó sì fi wọ́n sílẹ̀, ó lọ sí Betani. Níbẹ̀ ni ó dúró ní òru náà.

18 Ní òwúrọ̀ bí ó ṣe ń padà sí ìlú, ebi ń pa á.

19 Ó sì ṣàkíyèsí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lẹ́bàá ojú ọ̀nà, ó sì lọ wò ó bóyá àwọn èso wà lórí rẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹyọ kan, ewé nìkan ni ó wà lórí rẹ̀. Nígbà náà ni ó sì wí fún igi náà pé, “Kí èso má tún so lórí rẹ mọ́ láti òní lọ àti títí láé.” Lójúkan náà igi ọ̀pọ̀tọ́ náà sì gbẹ.

Read Matthew 21 in the app The whole chapter

Search the Scriptures

Choose a translation

KJVBSBWEBNHEBASVYLTDBYWBTBBEEBRGNVDRALUTCANRIVLSGRVABPMYORIGBSWATGLIRV