The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Leviticus 5

Leviticus 5:13

Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà fún èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, a ó sì dáríjì í: ìyókù sì jẹ́ ti àlùfáà, bí ẹbọ ohun jíjẹ.’ ”

Leviticus 5:13 · Bíbélì Mímọ́

← PreviousRead Leviticus 5Next →

Leviticus 5:13 in other translations

KJV King James Version

And the priest shall make an atonement for him as touching his sin that he hath sinned in one of these, and it shall be forgiven him: and the remnant shall be the priest's, as a meat offering.

BSB Berean Standard Bible

In this way the priest will make atonement for him for any of these sins he has committed, and he will be forgiven. The remainder will belong to the priest, like the grain offering.”

WEB World English Bible

The priest shall make atonement for him concerning his sin that he has sinned in any of these things, and he will be forgiven; and the rest shall be the priest’s, as the meal offering.’”

Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.

In context

10 Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wá rú ẹbọ sísun gẹ́gẹ́ bí ìlànà, yóò sì ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, a ó sì dáríjì í.

11 “ ‘Bí ó bá sì jẹ́ pé kò ní agbára àti mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì wá, kí ó mú ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, kò gbọdọ̀ fi òróró tàbí tùràrí sí i nítorí pé ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.

12 Kí ó gbé e wá sí ọ̀dọ̀ àlùfáà, àlùfáà yóò sì bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.

13 Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà fún èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, a ó sì dáríjì í: ìyókù sì jẹ́ ti àlùfáà, bí ẹbọ ohun jíjẹ.’ ”

14 Olúwa sọ fún Mose pé,

15 “Nígbà tí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ ìrékọjá tí ó sì ṣe láìmọ̀ ní ti àwọn ohun mímọ́ Olúwa, kí ó mú àgbò láti inú agbo ẹran wá fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ìtánràn, àgbò tí kò lábùkù tí ó sì níye lórí gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. Ẹbọ ẹ̀bi ni.

16 Kí ó ṣe àtúnṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀ nínú ti àwọn ohun mímọ́, kí ó sì fi ìdámárùn-ún kún iye rẹ̀, kí ó sì kó gbogbo rẹ̀ fún àlùfáà. Àlùfáà yóò sì fi àgbò ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ṣe ètùtù fún, a ó sì dáríjì í.

Read Leviticus 5 in the app The whole chapter

Search the Scriptures

Choose a translation

KJVBSBWEBNHEBASVYLTDBYWBTBBEEBRGNVDRALUTCANRIVLSGRVABPMYORIGBSWATGLIRV