The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Judges 21
Nítorí pé nígbà tí wọ́n ka àwọn ènìyàn, wọ́n rí i pé kò sí ẹnìkankan láti inú àwọn ará Jabesi Gileadi tí ó wà níbẹ̀.
Judges 21:9 · Bíbélì Mímọ́
← PreviousRead Judges 21Next →
For the people were numbered, and, behold, there were none of the inhabitants of Jabeshgilead there.
For when the people were counted, none of the residents of Jabesh-gilead were there.
For when the people were counted, behold, there were none of the inhabitants of Jabesh Gilead there.
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
6 Àwọn ọmọ Israẹli sì banújẹ́ fún àwọn arákùnrin wọn, àwọn ẹ̀yà Benjamini. Wọ́n wí pé, “A ti ké ẹ̀yà kan kúrò lára Israẹli lónìí.”
7 Báwo ni a yóò ṣe rí aya fún àwọn tí ó ṣẹ́kù, nítorí àwa ti fi Olúwa búra láti má fi ọ̀kankan nínú àwọn ọmọbìnrin wa fún wọn ní aya.
8 Wọ́n sì béèrè wí pé, “Èwo ni nínú ẹ̀yà Israẹli ni ó kọ̀ láti bá àwọn ènìyàn péjọ níwájú Olúwa ní Mispa?” Wọ́n rí i pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó wa láti Jabesi Gileadi tí ó wá sí ibùdó fún àjọ náà.
9 Nítorí pé nígbà tí wọ́n ka àwọn ènìyàn, wọ́n rí i pé kò sí ẹnìkankan láti inú àwọn ará Jabesi Gileadi tí ó wà níbẹ̀.
10 Àwọn ìjọ ènìyàn náà sì rán ẹgbàá mẹ́fà (12,000) àwọn jagunjagun ọkùnrin, lọ sí Jabesi Gileadi wọ́n fún wọn ní àṣẹ pé, ẹ lọ fi idà kọlu gbogbo àwọn tí ó wà níbẹ̀, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́.
11 Wọ́n ní, “Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe, ẹ pa gbogbo ọkùnrin àti gbogbo obìnrin tí kì í ṣe wúńdíá.”
12 Wọ́n rí àwọn irinwó (400) ọ̀dọ́bìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí nínú àwọn olùgbé Jabesi Gileadi, wọ́n sì mú wọn lọ sí ibùdó ní Ṣilo àwọn ará Kenaani.
Read Judges 21 in the app The whole chapter