The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Isaiah 30
ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóò rí fún ọ gẹ́gẹ́ bí ògiri gíga, tí ó sán tí ó sì fì tí ó sì wó lójijì, àti ní ìṣẹ́jú kan.
Isaiah 30:13 · Bíbélì Mímọ́
← PreviousRead Isaiah 30Next →
Therefore this iniquity shall be to you as a breach ready to fall, swelling out in a high wall, whose breaking cometh suddenly at an instant.
this iniquity of yours is like a breach about to fail, a bulge in a high wall, whose collapse will come suddenly— in an instant!
therefore this iniquity shall be to you like a breach ready to fall, swelling out in a high wall, whose breaking comes suddenly in an instant.
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
10 Wọ́n sọ fún àwọn aríran pé, “Ẹ má ṣe rí ìran mọ́!” Àti fún àwọn wòlíì, “Ẹ má ṣe fi ìran ohun tí ó tọ́ hàn wá mọ́! Ẹ sọ ohun tí ó tura fún wa, ẹ sàsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn.
11 Ẹ fi ọ̀nà yìí sílẹ̀, ẹ kúrò ní ọ̀nà yìí ẹ dẹ́kun à ń dojú ìjà kọ wá pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ Israẹli!”
12 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ẹni Mímọ́ Israẹli wí: “Nítorí pé ẹ ti kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀, ẹ gbára lé ìnilára kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé ẹ̀tàn,
13 ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóò rí fún ọ gẹ́gẹ́ bí ògiri gíga, tí ó sán tí ó sì fì tí ó sì wó lójijì, àti ní ìṣẹ́jú kan.
14 Yóò sì fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ bí àpáàdì tí a fọ́ pátápátá àti pé a kò ní rí ẹ̀rún kan nínú àfọ́kù rẹ̀, fún mímú èédú kúrò nínú ààrò tàbí gbígbọ́n omi jáde kúrò nínú àmù.”
15 Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli wí: “Nínú ìrònúpìwàdà àti ìsinmi ni ìgbàlà rẹ wà, ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ni agbára rẹ wà, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò ní ọ̀kankan nínú wọn.
16 Ẹ̀yin wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò sálọ lórí ẹṣin.’ Nítorí náà ẹ̀yin yóò sá! Ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa yóò gun àwọn ẹṣin tí ó yára lọ.’ Nítorí náà àwọn tí ń lé e yín yóò yára!
Read Isaiah 30 in the app The whole chapter