The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Acts 7
Ẹni tí ó rí ojúrere níwájú Ọlọ́run, tí ó sì tọrọ láti rí ibùgbé fún Ọlọ́run Jakọbu.
Acts 7:46 · Bíbélì Mímọ́
Who found favour before God, and desired to find a tabernacle for the God of Jacob.
who found favor in the sight of God and asked to provide a dwelling place for the God of Jacob.
who found favor in the sight of God, and asked to find a habitation for the God of Jacob.
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
43 Ẹ̀yin sì tẹ́wọ́gbà àgọ́ Moleki, àti ìràwọ̀ Refani òrìṣà yín, àwòrán tí ẹ̀yin ṣe láti máa bọ wọ́n. Nítorí náà èmi yóò kó yín lọ sí ìgbèkùn rékọjá Babeli.’
44 “Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí pẹ̀lú wọn ní ijù. Èyí tí a ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó ba Mose sọ̀rọ̀ pé kí ó ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí ó ti rí.
45 Ti àwọn baba wa tí ó tẹ̀lé wọn sí mú bá Joṣua wá sí ilẹ̀ ìní àwọn aláìkọlà, tí Ọlọ́run lè jáde kúrò níwájú àwọn baba wa, títí dí àkókò Dafidi.
46 Ẹni tí ó rí ojúrere níwájú Ọlọ́run, tí ó sì tọrọ láti rí ibùgbé fún Ọlọ́run Jakọbu.
47 Ṣùgbọ́n Solomoni ni ó kọ́ ilé fún un.
48 “Ṣùgbọ́n Ọ̀gá-ògo kì í gbé ilé ti a fi ọwọ́ kọ́, gẹ́gẹ́ bí wòlíì ti wí pé:
49 “ ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé ni àpótí ìtìsẹ̀ mi. Irú ilé kín ní ẹ̀yin yóò kọ́ fún mi? ni Olúwa wí. Tàbí níbo ni yóò jẹ́ ibi ìsinmi mi?
Read Acts 7 in the app The whole chapter