The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Acts 23
Àwọn tí ó dúró tì Paulu sì wí pé, “Ìwọ́ ń gan olórí àlùfáà Ọlọ́run?”
Acts 23:4 · Bíbélì Mímọ́
And they that stood by said, Revilest thou God's high priest?
But those standing nearby said, “How dare you insult the high priest of God!”
Those who stood by said, “Do you malign God’s high priest?”
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
1 Paulu tẹjúmọ́ ìgbìmọ̀, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi tí ń fi gbogbo ẹ̀rí ọkàn rere lo ayé mi níwájú Ọlọ́run títí fi di òní yìí.”
2 Nígbà yìí ni Anania olórí àlùfáà pàṣẹ fún àwọn tí ó dúró tí Paulu pé, kí wọn ó gbá a lẹ́nu.
3 Nígbà náà ni Paulu wí fún un pé, “Ọlọ́run yóò lù ọ́, ìwọ ògiri tí a kùn lẹ́fun: ìwọ jókòó láti dá mi lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin, ṣùgbọ́n ìwọ gan an rú òfin nípa pípàṣẹ pé kí a lù mí!”
4 Àwọn tí ó dúró tì Paulu sì wí pé, “Ìwọ́ ń gan olórí àlùfáà Ọlọ́run?”
5 Paulu sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi kò mọ̀ pé olórí àlùfáà ni: nítorí a tí kọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ olórí àwọn ènìyàn rẹ̀ ní búburú.’ ”
6 Ṣùgbọ́n nígbà tí Paulu ṣàkíyèsí pé, apá kan wọn jẹ́ Sadusi, apá kan sì jẹ́ Farisi, ó kígbe ní ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi jẹ́ Farisi, ọmọ Farisi sì ni èmi. Mo dúró ní ìdájọ́ nítorí ìrètí mi nínú àjíǹde òkú.”
7 Nígbà tí ó sì tí wí èyí, ìyapa dé láàrín àwọn Farisi àti àwọn Sadusi: àjọ sì pín sì méjì.
Read Acts 23 in the app The whole chapter