The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Proverbs 5
Nítorí ètè àwọn àjèjì obìnrin a máa sun bi oyin, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì kúnná ju òróró lọ.
Proverbs 5:3 · Bíbélì Mímọ́
← PreviousRead Proverbs 5Next →
For the lips of a strange woman drop as an honeycomb, and her mouth is smoother than oil:
Though the lips of the forbidden woman drip honey and her speech is smoother than oil,
For the lips of an adulteress drip honey. Her mouth is smoother than oil,
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
1 Ọmọ mi, fiyèsí ọgbọ́n mi, kí o sì dẹtí rẹ sí òye mi,
2 kí ìwọ sì lè ní ìṣọ́ra kí ètè rẹ sì le pa ìmọ̀ mọ́.
3 Nítorí ètè àwọn àjèjì obìnrin a máa sun bi oyin, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì kúnná ju òróró lọ.
4 Ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, ó korò ju òróǹró lọ, ó mú bí idà olójú méjì.
5 Ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà ikú ìgbésẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí ibojì òkú.
6 Kí ìwọ má ba à já ipa ọ̀nà ìyè; ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla, ṣùgbọ́n kò tilẹ̀ mọ́.
Read Proverbs 5 in the app The whole chapter