The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Numbers 2
Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlógójì ó lé ẹgbẹ̀ta (74,600).
Numbers 2:4 · Bíbélì Mímọ́
← PreviousRead Numbers 2Next →
And his host, and those that were numbered of them, were threescore and fourteen thousand and six hundred.
and his division numbers 74,600.
His division, and those who were counted of them, were seventy-four thousand six hundred.
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
1 Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé,
2 “Kí àwọn ọmọ Israẹli pa àgọ́ wọn yí àgọ́ ìpàdé ká, kí wọ́n jẹ́ kí àgọ́ wọn jìnnà sí i díẹ̀, oníkálùkù lábẹ́ ọ̀págun pẹ̀lú àsíá ìdílé wọn.”
3 Ní ìlà-oòrùn, ní ìdojúkọ àtiyọ oòrùn: ni kí ìpín ti Juda pa ibùdó wọn sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Juda ni Nahiṣoni ọmọ Amminadabu.
4 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlógójì ó lé ẹgbẹ̀ta (74,600).
5 Ẹ̀yà Isakari ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Isakari ni Netaneli ọmọ Suari.
6 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó lé irinwó (54,400).
7 Ẹ̀yà Sebuluni ni yóò tẹ̀lé e. Olórí Sebuluni ni Eliabu ọmọ Heloni.
Read Numbers 2 in the app The whole chapter