The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Numbers 11

Numbers 11:21

Ṣùgbọ́n Mose sọ pé, “Mo wà láàrín ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ènìyàn (600,000) ni ìrìnkiri, ó sì sọ pé, ‘Èmi ó fún wọn ní ẹran láti jẹ fún oṣù kan gbáko!’

Numbers 11:21 · Bíbélì Mímọ́

← PreviousRead Numbers 11Next →

Numbers 11:21 in other translations

KJV King James Version

And Moses said, The people, among whom I am, are six hundred thousand footmen; and thou hast said, I will give them flesh, that they may eat a whole month.

BSB Berean Standard Bible

But Moses replied, “Here I am among 600,000 men on foot, yet You say, ‘I will give them meat, and they will eat for a month.’

WEB World English Bible

Moses said, “The people, among whom I am, are six hundred thousand men on foot; and you have said, ‘I will give them meat, that they may eat a whole month.’

Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.

In context

18 “Sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ ní ìmúrasílẹ̀ fún ọ̀la, ẹ ó sì jẹ ẹran. Nítorí pé Olúwa ti gbọ́ igbe ẹkún yín, èyí tí ẹ sun pé, “Ìbá ṣe pé a lè rí ẹran jẹ ni! Ó sàn fún wa ní Ejibiti jù báyìí lọ!” Nítorí náà ni Olúwa yóò fi fún yín ní ẹran, ẹ ó sì jẹ ẹ́.

19 Ẹ kò ní i jẹ ẹ́ fún ọjọ́ kan, ọjọ́ méjì, ọjọ́ márùn-ún, ọjọ́ mẹ́wàá tàbí ogúnjọ́ lásán,

20 ṣùgbọ́n fún odidi oṣù kan, títí tí ẹran náà yóò fi máa yọ ní imú yín, tí yóò sì sú yín, nítorí pé ẹ ti kẹ́gàn Olúwa tí ó wà láàrín yín, ẹ sì ti sọkún fún un wí pé, “Kí ló dé tí a fi kúrò ní Ejibiti gan an?” ’ ”

21 Ṣùgbọ́n Mose sọ pé, “Mo wà láàrín ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ènìyàn (600,000) ni ìrìnkiri, ó sì sọ pé, ‘Èmi ó fún wọn ní ẹran láti jẹ fún oṣù kan gbáko!’

22 Ǹjẹ́ bí a tilẹ̀ pa àgbò ẹran àti ọmọ ẹran, yóò ha tó wọn bí? Tàbí bí a tilẹ̀ pa gbogbo ẹja inú omi fún wọn, yóò wa tó bí?”

23 Olúwa sì dá Mose lóhùn pé, “Ọwọ́ Olúwa ha kúrú bí? Ìwọ yóò ri nísinsin yìí bóyá ọ̀rọ̀ tí mo sọ yóò ṣẹ tàbí kò ni í ṣẹ.”

24 Mose sì jáde, ó sọ ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn. Ó mú àwọn àádọ́rin àgbàgbà Israẹli dúró yí àgọ́ ká.

Read Numbers 11 in the app The whole chapter

Search the Scriptures

Choose a translation

KJVBSBWEBNHEBASVYLTDBYWBTBBEEBRGNVDRALUTCANRIVLSGRVABPMYORIGBSWATGLIRV