The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Matthew 21
Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tẹ́ aṣọ wọn sí ojú ọ̀nà níwájú rẹ̀, ẹlòmíràn ṣẹ́ ẹ̀ka igi wẹ́wẹ́ wọ́n sì tẹ́ wọn sí ojú ọ̀nà.
Matthew 21:8 · Bíbélì Mímọ́
← PreviousRead Matthew 21Next →
And a very great multitude spread their garments in the way; others cut down branches from the trees, and strawed them in the way.
A massive crowd spread their cloaks on the road, while others cut branches from the trees and spread them on the road.
A very great multitude spread their clothes on the road. Others cut branches from the trees and spread them on the road.
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
5 “Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Sioni pé, ‘Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, ní ìrẹ̀lẹ̀, ó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.’ ”
6 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sí lọ, wọ́n ṣe bí Jesu ti sọ fún wọn.
7 Wọ́n sì mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, wọ́n tẹ́ aṣọ lé e, Jesu si jókòó lórí rẹ̀.
8 Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tẹ́ aṣọ wọn sí ojú ọ̀nà níwájú rẹ̀, ẹlòmíràn ṣẹ́ ẹ̀ka igi wẹ́wẹ́ wọ́n sì tẹ́ wọn sí ojú ọ̀nà.
9 Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ níwájú rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀ pẹ̀lú ń kígbe pé, “Hosana fún ọmọ Dafidi!” “Olùbùkún ni fún ẹni tí ó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa!” “Hosana ní ibi gíga jùlọ!”
10 Bí Jesu sì ti ń wọ Jerusalẹmu, gbogbo ìlú mì tìtì, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara wọn pé, “Ta nìyìí?”
11 Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì dáhùn pé, “Èyí ni Jesu, wòlíì náà láti Nasareti ti Galili.”
Read Matthew 21 in the app The whole chapter