The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Matthew 13
Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ọmọ Ènìyàn ni ẹni tí ó ń fúnrúgbìn rere.
Matthew 13:37 · Bíbélì Mímọ́
← PreviousRead Matthew 13Next →
He answered and said unto them, He that soweth the good seed is the Son of man;
He replied, “The One who sows the good seed is the Son of Man.
He answered them, “He who sows the good seed is the Son of Man,
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
34 Òwe ni Jesu fi sọ nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, òwe ni ó fi bá wọn sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tó sọ.
35 Kí ọ̀rọ̀ tí a ti ẹnu àwọn wòlíì sọ lé wá sí ìmúṣẹ pé: “Èmi yóò ya ẹnu mi láti fi òwe sọ̀rọ̀. Èmi yóò sọ àwọn ohun tí ó fi ara sin láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá.”
36 Lẹ́yìn náà ó sì fi ọ̀pọ̀ ènìyàn sílẹ̀ lóde, ó wọ ilé lọ. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn wí pé, “Ṣàlàyé òwe èpò inú oko fún wa.”
37 Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ọmọ Ènìyàn ni ẹni tí ó ń fúnrúgbìn rere.
38 Ayé ni oko náà; irúgbìn rere ni àwọn ènìyàn ti ìjọba ọ̀run. Èpò ni àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ti èṣù,
39 ọ̀tá tí ó gbin àwọn èpò sáàrín alikama ni èṣù. Ìkórè ni òpin ayé, àwọn olùkórè sì ní àwọn angẹli.
40 “Gẹ́gẹ́ bí a ti kó èpò jọ, tí a sì sun ún nínú iná, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí ní ìgbẹ̀yìn ayé.
Read Matthew 13 in the app The whole chapter