The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Mark 12
àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu àti ipò ọlá níbi àsè.
Mark 12:39 · Bíbélì Mímọ́
And the chief seats in the synagogues, and the uppermost rooms at feasts:
and to have the chief seats in the synagogues and the places of honor at banquets.
and to get the best seats in the synagogues and the best places at feasts,
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
36 Nítorí tí Dafidi tìkára rẹ̀, ti ń ti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ sọ̀rọ̀ wí pé: “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé: “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’
37 Níwọ́n ìgbà tí Dafidi tìkára rẹ̀ pè é ní ‘Olúwa,’ báwo ni ó túnṣe lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?” Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.
38 Ó sì wí fún wọn nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣọ́ra fun àwọn olùkọ́ òfin tí wọ́n fẹ́ láti máa wọ aṣọ gígùn káàkiri, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà,
39 àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu àti ipò ọlá níbi àsè.
40 Àwọn tí wọ́n jẹ ilé àwọn opó rún, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn, nítorí èyí, ìjìyà wọn yóò pọ̀ púpọ̀.”
41 Jesu jókòó ní òdìkejì kọjú sí àpótí ìṣúra: ó ń wo ìjọ ènìyàn ti ń sọ owó sínú àpótí ìṣúra, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì sọ púpọ̀ sí i.
42 Ṣùgbọ́n obìnrin opó kan wà, ó sì fi ààbọ̀ owó idẹ méjì síbẹ̀, tí ì ṣe ìdá méjì owó-babà kan sínú rẹ̀.
Read Mark 12 in the app The whole chapter