The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Leviticus 6

Leviticus 6:21

Ẹ pèsè rẹ̀ pẹ̀lú òróró nínú àwo fífẹ̀, ẹ pò ó pọ̀ dáradára, kí ẹ sì gbé ọrẹ ohun jíjẹ náà wá ní ègé kéékèèké bí òórùn dídùn sí Olúwa.

Leviticus 6:21 · Bíbélì Mímọ́

← PreviousRead Leviticus 6Next →

Leviticus 6:21 in other translations

KJV King James Version

In a pan it shall be made with oil; and when it is baken, thou shalt bring it in: and the baken pieces of the meat offering shalt thou offer for a sweet savour unto the LORD.

BSB Berean Standard Bible

It shall be prepared with oil on a griddle; you are to bring it well-kneaded and present it as a grain offering broken in pieces, a pleasing aroma to the LORD.

WEB World English Bible

It shall be made with oil in a griddle. When it is soaked, you shall bring it in. You shall offer the meal offering in baked pieces for a pleasant aroma to the LORD.

Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.

In context

18 Èyíkéyìí nínú àwọn ọmọkùnrin ìran Aaroni ló le jẹ ẹ́. Èyí ni ìpín rẹ tí ó gbọdọ̀ máa ṣe déédé lára àwọn ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa láti ìrandíran. Ohunkóhun tí ó bá kàn án yóò di mímọ́.’ ”

19 Olúwa sọ fún Mose pé,

20 “Èyí ni ọrẹ tí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa ní ọjọ́ tí a bá fi òróró yan ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn; ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára fún ẹbọ ohun jíjẹ lójoojúmọ́, ìdajì rẹ̀ ní àárọ̀ àti ìdajì rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́.

21 Ẹ pèsè rẹ̀ pẹ̀lú òróró nínú àwo fífẹ̀, ẹ pò ó pọ̀ dáradára, kí ẹ sì gbé ọrẹ ohun jíjẹ náà wá ní ègé kéékèèké bí òórùn dídùn sí Olúwa.

22 Ọmọkùnrin Aaroni tí yóò rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tí a fi òróró yàn ni yóò rú ẹbọ náà. Ó jẹ́ ìpín ti Olúwa títí láé, wọn sì gbọdọ̀ sun ún pátápátá.

23 Gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ ti àlùfáà ni wọ́n gbọdọ̀ sun pátápátá, wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.”

Read Leviticus 6 in the app The whole chapter

Search the Scriptures

Choose a translation

KJVBSBWEBNHEBASVYLTDBYWBTBBEEBRGNVDRALUTCANRIVLSGRVABPMYORIGBSWATGLIRV