The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Leviticus 21

Leviticus 21:7

“ ‘Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ fẹ́ panṣágà tàbí obìnrin tí ó ti fi ọkùnrin ba ara rẹ̀ jẹ́ tàbí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ ti kọ̀sílẹ̀ nítorí pé àwọn àlùfáà jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run wọn.

Leviticus 21:7 · Bíbélì Mímọ́

← PreviousRead Leviticus 21Next →

Leviticus 21:7 in other translations

KJV King James Version

They shall not take a wife that is a whore, or profane; neither shall they take a woman put away from her husband: for he is holy unto his God.

BSB Berean Standard Bible

A priest must not marry a woman defiled by prostitution or divorced by her husband, for the priest is holy to his God.

WEB World English Bible

“‘They shall not marry a woman who is a prostitute, or profane. A priest shall not marry a woman divorced from her husband; for he is holy to his God.

Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.

In context

4 Nítorí tí ó jẹ́ olórí, òun kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ ba ara rẹ̀ jẹ́ láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

5 “ ‘Àlùfáà kò gbọdọ̀ fá irun orí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ rẹ́ irùngbọ̀n rẹ̀. Kò gbọdọ̀ fi abẹ ya ara rẹ̀ láti fihàn pé òun wà ní ipò ọ̀fọ̀.

6 Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún Ọlọ́run, kí wọ́n má ba à sọ orúkọ Ọlọ́run wọn di àìmọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń fi iná sun ẹbọ sí Olúwa wọn, ti ó jẹ oúnjẹ Ọlọ́run wọn. Nítorí náà wọn gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́.

7 “ ‘Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ fẹ́ panṣágà tàbí obìnrin tí ó ti fi ọkùnrin ba ara rẹ̀ jẹ́ tàbí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ ti kọ̀sílẹ̀ nítorí pé àwọn àlùfáà jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run wọn.

8 Àwọn ènìyàn gbọdọ̀ máa kà wọ́n sí mímọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń rú ẹbọ oúnjẹ fún mi. Èmi ni Olúwa, mo jẹ́ mímọ́, mo sì ya àwọn ènìyàn mi sí mímọ́.

9 “ ‘Bí ọmọbìnrin àlùfáà kan bá fi iṣẹ́ àgbèrè ba ara rẹ̀ jẹ́, ó dójútì baba rẹ̀, iná ni a ó dá sun ún.

10 “ ‘Lẹ́yìn tí a ti fi òróró yan olórí àlùfáà láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀, tí a sì ti fi àmì òróró yàn án láti máa wọ aṣọ àlùfáà, ó gbọdọ̀ tọ́jú irun orí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fa aṣọ rẹ̀ ya láti fihàn pé òun wà ní ipò ọ̀fọ̀.

Read Leviticus 21 in the app The whole chapter

Search the Scriptures

Choose a translation

KJVBSBWEBNHEBASVYLTDBYWBTBBEEBRGNVDRALUTCANRIVLSGRVABPMYORIGBSWATGLIRV