The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Leviticus 19

Leviticus 19:21

Kí ọkùnrin náà mú àgbò kan wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé bí i ẹbọ ẹ̀bi sí Olúwa.

Leviticus 19:21 · Bíbélì Mímọ́

← PreviousRead Leviticus 19Next →

Leviticus 19:21 in other translations

KJV King James Version

And he shall bring his trespass offering unto the LORD, unto the door of the tabernacle of the congregation, even a ram for a trespass offering.

BSB Berean Standard Bible

The man, however, must bring a ram to the entrance to the Tent of Meeting as his guilt offering to the LORD.

WEB World English Bible

He shall bring his trespass offering to the LORD, to the door of the Tent of Meeting, even a ram for a trespass offering.

Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.

In context

18 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san: má sì ṣe bínú sí èyíkéyìí nínú àwọn ènìyàn rẹ. Ṣùgbọ́n, kí ìwọ kí ó fẹ́ ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ. Èmi ni Olúwa.

19 “ ‘Máa pa àṣẹ mi mọ́. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ohun ọ̀sìn rẹ máa gùn pẹ̀lú ẹ̀yà mìíràn. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbin dàrúdàpọ̀ oríṣìí irúgbìn méjì sínú oko kan. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ wọ aṣọ èyí tí a fi oríṣìí ohun èlò ìhunṣọ méjì ṣe.

20 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá obìnrin tí ó jẹ́ ẹrú lòpọ̀, ẹni tí a ti mọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn tí a kò sì tí ì rà á padà tàbí sọ ọ́ di òmìnira. Ẹ gbọdọ̀ ṣe ìwádìí kí ẹ sì jẹ wọ́n ní ìyà tó tọ́ ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ pa wọ́n, torí pé kò ì tí ì di òmìnira.

21 Kí ọkùnrin náà mú àgbò kan wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé bí i ẹbọ ẹ̀bi sí Olúwa.

22 Àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú àgbò ẹbọ ẹ̀bi náà níwájú Olúwa fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀. A ó sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ náà jì í.

23 “ ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí ẹ sì gbin igi eléso, kí ẹ ká èso wọn sí ohun èèwọ̀. Fún ọdún mẹ́ta ni kí ẹ kà á sí èèwọ̀, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.

24 Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹrin, gbogbo èso wọ̀nyí yóò jẹ́ mímọ́, ọrẹ fún ìyìn Olúwa.

Read Leviticus 19 in the app The whole chapter

Search the Scriptures

Choose a translation

KJVBSBWEBNHEBASVYLTDBYWBTBBEEBRGNVDRALUTCANRIVLSGRVABPMYORIGBSWATGLIRV