The Bible › Bíbélì Mímọ́ › John 12
Ní ìsinsin yìí ni ìdájọ́ ayé yìí dé: nísinsin yìí ni a ó lé aládé ayé yìí jáde.
John 12:31 · Bíbélì Mímọ́
Now is the judgment of this world: now shall the prince of this world be cast out.
Now judgment is upon this world; now the prince of this world will be cast out.
Now is the judgment of this world. Now the prince of this world will be cast out.
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
28 Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo!” Nígbà náà ni ohùn kan ti ọ̀run wá, wí pé, “Èmi ti ṣe é lógo!”
29 Nítorí náà ìjọ ènìyàn tí ó dúró níbẹ̀, tí wọ́n sì gbọ́ ọ, wí pé, “Àrá ń sán.” Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Angẹli kan ni ó ń bá a sọ̀rọ̀.”
30 Jesu sì dáhùn wí pé, “Kì í ṣe nítorí mi ni ohùn yìí ṣe wá, bí kò ṣe nítorí yín.
31 Ní ìsinsin yìí ni ìdájọ́ ayé yìí dé: nísinsin yìí ni a ó lé aládé ayé yìí jáde.
32 Àti èmi, bí a bá gbé mi sókè kúrò ní ayé, èmi ó fa gbogbo ènìyàn sọ́dọ̀ ara mi!”
33 Ṣùgbọ́n ó wí èyí, ó ń ṣe àpẹẹrẹ irú ikú tí òun yóò kú.
34 Nítorí náà àwọn ìjọ ènìyàn dá a lóhùn pé, “Àwa gbọ́ nínú òfin pé, Kristi wà títí láéláé, ìwọ ha ṣe wí pé, ‘A ó gbé Ọmọ Ènìyàn sókè’? Ta ni ó ń jẹ́ ‘Ọmọ Ènìyàn yìí’?”
Read John 12 in the app The whole chapter