The Bible › Bíbélì Mímọ́ › John 1
Àwọn ọmọ tí kì í ṣe nípa ẹ̀jẹ̀, tàbí nípa ti ìfẹ́ ara, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípa ìfẹ́ ti ènìyàn, bí kò ṣe láti ọwọ́ Ọlọ́run.
John 1:13 · Bíbélì Mímọ́
Which were born, not of blood, nor of the will of the flesh, nor of the will of man, but of God.
children born not of blood, nor of the desire or will of man, but born of God.
who were born, not of blood, nor of the will of the flesh, nor of the will of man, but of God.
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
10 Òun sì wà ní ayé, àti pé, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a sì ti dá ayé, ṣùgbọ́n ayé kò sì mọ̀ ọ́n.
11 Ó tọ àwọn tirẹ̀ wá, àwọn tirẹ̀ kò sì gbà á.
12 Ṣùgbọ́n iye àwọn tí ó gbà á, àní àwọn náà tí ó gbà orúkọ rẹ̀ gbọ́, àwọn ni ó fi ẹ̀tọ́ fún láti di ọmọ Ọlọ́run.
13 Àwọn ọmọ tí kì í ṣe nípa ẹ̀jẹ̀, tàbí nípa ti ìfẹ́ ara, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípa ìfẹ́ ti ènìyàn, bí kò ṣe láti ọwọ́ Ọlọ́run.
14 Ọ̀rọ̀ náà sì di ara, òun sì ń bá wa gbé. Àwa sì ti rí ògo rẹ̀, àní ògo ọmọ rẹ kan ṣoṣo, tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́.
15 Johanu sì jẹ́rìí nípa rẹ̀, ó kígbe, ó sì wí pé, “Èyí ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ‘Ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi pọ̀jù mí lọ, nítorí òun ti wà ṣáájú mi.’ ”
16 Nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ni gbogbo wa sì ti gba ìbùkún kún ìbùkún.
Read John 1 in the app The whole chapter