The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Isaiah 45

Isaiah 45:13

Èmi yóò gbé Kirusi sókè nínú òdodo mi. Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́. Òun yóò tún ìlú mi kọ́ yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”

Isaiah 45:13 · Bíbélì Mímọ́

← PreviousRead Isaiah 45Next →

Isaiah 45:13 in other translations

KJV King James Version

I have raised him up in righteousness, and I will direct all his ways: he shall build my city, and he shall let go my captives, not for price nor reward, saith the LORD of hosts.

BSB Berean Standard Bible

I will raise up Cyrus in righteousness, and I will make all his ways straight. He will rebuild My city and set My exiles free, but not for payment or reward, says the LORD of Hosts.”

WEB World English Bible

I have raised him up in righteousness, and I will make all his ways straight. He shall build my city, and he shall let my exiles go free, not for price nor reward,” says the LORD of Armies.

Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.

In context

10 Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé, ‘Kí ni o bí?’ tàbí sí ìyá rẹ̀, ‘Kí ni ìwọ ti bí?’

11 “Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Ẹni Mímọ́ Israẹli, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Nípa ohun tí ó ń bọ̀, ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi, tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí?

12 Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayé tí ó sì da ọmọ ènìyàn sórí i rẹ̀. Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run; mo sì kó àwọn àgbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta.

13 Èmi yóò gbé Kirusi sókè nínú òdodo mi. Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́. Òun yóò tún ìlú mi kọ́ yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”

14 Ohun tí Olúwa wí nìyìí: “Àwọn èròjà ilẹ̀ Ejibiti àti àwọn ọjà ilẹ̀ Kuṣi, àti àwọn Sabeani— wọn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ wọn yóò sì jẹ́ tìrẹ; wọn yóò máa wọ́ tẹ̀lé ọ lẹ́yìn, wọn yóò máa wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́. Wọn yóò máa foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀, wọn yóò sì máa bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ pé, ‘Nítòótọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ kò sì ṣí ẹlòmíràn; kò sí ọlọ́run mìíràn.’ ”

15 Nítòótọ́ ìwọ jẹ́ Ọlọ́run tí ó fi ara rẹ̀ pamọ́, Ìwọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà Israẹli,

16 Gbogbo àwọn tí ó ń gbẹ́ ère ni ojú yóò tì wọn yóò sì kan àbùkù; gbogbo wọn ni yóò bọ́ sínú àbùkù papọ̀.

Read Isaiah 45 in the app The whole chapter

Search the Scriptures

Choose a translation

KJVBSBWEBNHEBASVYLTDBYWBTBBEEBRGNVDRALUTCANRIVLSGRVABPMYORIGBSWATGLIRV