The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Hosea 2
“Èmi yóò sì dáhùn ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí; “Èmi yóò dá àwọn ọ̀run lóhùn àwọn ọ̀run yóò sì dá ilẹ̀ lóhùn;
Hosea 2:21 · Bíbélì Mímọ́
And it shall come to pass in that day, I will hear, saith the LORD, I will hear the heavens, and they shall hear the earth;
“On that day I will respond—” declares the LORD— “I will respond to the heavens, and they will respond to the earth.
It will happen in that day, that I will respond,” says the LORD. “I will respond to the heavens, and they will respond to the earth;
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
18 Ní ọjọ́ náà, èmi yóò ṣe májẹ̀mú fún wọn àti àwọn ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹ̀dá tí ń rìn lórí ilẹ̀. Kí wọn má bà á bẹ̀rù ara wọn mọ́. Ọfà, idà àti ogun jíjà ni èmi ó parun ní ilẹ̀ náà kí gbogbo ènìyàn bá a lè wà ní àìléwu.
19 Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi títí láé; Èmi ó fẹ́ ọ ní ìwà òdodo àti òtítọ́, ní ìfẹ́ àti àánú.
20 Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi ní òtítọ́ ìwọ yóò sì mọ Olúwa.
21 “Èmi yóò sì dáhùn ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí; “Èmi yóò dá àwọn ọ̀run lóhùn àwọn ọ̀run yóò sì dá ilẹ̀ lóhùn;
22 ilẹ̀ náà yóò sì dá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró lóhùn Gbogbo wọn ó sì dá Jesreeli lóhùn.
23 Èmi ó sì gbìn ín fún ara mi lórí ilẹ̀ náà, Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí kò tì í ri ‘Àánú gbà.’ Èmi yóò sọ fún àwọn tí ‘Kì í ṣe ènìyàn mi pé,’ ‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi’; àwọn náà yóò sì wí pé, ‘Ìwọ ni Ọlọ́run mi.’ ”
Read Hosea 2 in the app The whole chapter