The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Acts 2
Nítorí náà àwọn tí ó fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ a bamitiisi wọn, lọ́jọ́ náà a sì kà ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkàn kún wọn.
Acts 2:41 · Bíbélì Mímọ́
Then they that gladly received his word were baptized: and the same day there were added unto them about three thousand souls.
Those who embraced his message were baptized, and about three thousand were added to the believers that day.
Then those who gladly received his word were baptized. There were added that day about three thousand souls.
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
38 Peteru sì wí fún wọn pé, “Ẹ ronúpìwàdà, kí a sì bamitiisi olúkúlùkù yín ní orúkọ Jesu Kristi fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ̀yin yóò sì gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́.
39 Nítorí fún yín ni ìlérí náà, àti fún àwọn ọmọ yín, àti fún gbogbo àwọn tí ó jìnnà réré, àní gbogbo àwọn tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò pè.”
40 Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ púpọ̀ mìíràn ni ó fi ń kìlọ̀ tí ó sì ń fi ń rọ̀ wọ́n wí pé, “Ẹ gba ara yín là lọ́wọ́ ìran àrékérekè yìí.”
41 Nítorí náà àwọn tí ó fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ a bamitiisi wọn, lọ́jọ́ náà a sì kà ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkàn kún wọn.
42 Wọ́n sì dúró ṣinṣin nínú ẹ̀kọ́ àwọn aposteli, àti ní ìdàpọ̀, ní bíbu àkàrà àti nínú àdúrà.
43 Ẹ̀rù sí ba gbogbo ọkàn; iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì púpọ̀ ni a ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe.
44 Gbogbo àwọn tí ó sì gbàgbọ́ wà ni ibìkan, wọn ní ohun gbogbo sọ́kàn;
Read Acts 2 in the app The whole chapter