The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Acts 13
Nípa rẹ̀ ni a ń dá olúkúlùkù ẹni tí ó gbàgbọ́ láre kúrò nínú ohun gbogbo, tí a kò lè dá yín láre rẹ̀ nínú òfin Mose.
Acts 13:39 · Bíbélì Mímọ́
And by him all that believe are justified from all things, from which ye could not be justified by the law of Moses.
Through Him everyone who believes is justified from everything you could not be justified from by the law of Moses.
and by him everyone who believes is justified from all things, from which you could not be justified by the law of Moses.
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
36 “Nítorí lẹ́yìn ìgbà ti Dafidi ti sin ìran rẹ tan nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sùn, a sì tẹ́ ẹ ti àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ sì rí ìdíbàjẹ́.
37 Ṣùgbọ́n ẹni tí Ọlọ́run jí dìde kò rí ìdíbàjẹ́.
38 “Ǹjẹ́ kí ó yé yín, ará pé nípasẹ̀ Jesu yìí ni a ń wàásù ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín.
39 Nípa rẹ̀ ni a ń dá olúkúlùkù ẹni tí ó gbàgbọ́ láre kúrò nínú ohun gbogbo, tí a kò lè dá yín láre rẹ̀ nínú òfin Mose.
40 Nítorí náà, ẹ kíyèsára, kí èyí tí a ti sọ nínú ìwé àwọn wòlíì má ṣe dé bá yín pé:
41 “ ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, kí ẹnu sì yà yín, kí a sì fẹ́ yín kù; nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín, tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́, bí a tilẹ̀ sọ fún yin.’ ”
42 Bí Paulu àti Barnaba sì ti ń jáde láti inú Sinagọgu, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé kí a sọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí i fún wọn lọ́jọ́ ìsinmi tí ń bọ̀.
Read Acts 13 in the app The whole chapter