The Bible › Bíbélì Mímọ́ › Acts 13
Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyìí pé: “ ‘Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dafidi, tí ó dájú.’
Acts 13:34 · Bíbélì Mímọ́
And as concerning that he raised him up from the dead, now no more to return to corruption, he said on this wise, I will give you the sure mercies of David.
In fact, God raised Him from the dead, never to see decay. As He has said: ‘I will give you the holy and sure blessings promised to David.’
“Concerning that he raised him up from the dead, now no more to return to corruption, he has spoken thus: ‘I will give you the holy and sure blessings of David.’
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
31 o sì farahàn lọ́jọ́ púpọ̀ fún àwọn tí ó bá a gòkè láti Galili wá sí Jerusalẹmu, àwọn tí í ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ nísinsin yìí fún àwọn ènìyàn.
32 “Àwa sì mú ìyìnrere wá fún yín pé, ìlérí èyí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn baba wa,
33 èyí ni Ọlọ́run ti mú ṣẹ fún àwa ọmọ wọn, nípa gbígbé Jesu dìde, bí a sì ti kọ̀wé rẹ̀ nínú Saamu kejì pé, “ ‘Ìwọ ni Ọmọ mi; lónìí ni mo bí ọ.’
34 Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyìí pé: “ ‘Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dafidi, tí ó dájú.’
35 Nítorí ó sì wí nínú Saamu mìíràn pẹ̀lú pé, “ ‘Ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.’
36 “Nítorí lẹ́yìn ìgbà ti Dafidi ti sin ìran rẹ tan nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sùn, a sì tẹ́ ẹ ti àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ sì rí ìdíbàjẹ́.
37 Ṣùgbọ́n ẹni tí Ọlọ́run jí dìde kò rí ìdíbàjẹ́.
Read Acts 13 in the app The whole chapter