The Bible › Bíbélì Mímọ́ › 2 Chronicles 6

2 Chronicles 6:39

nígbà náà, láti ọ̀run, ibi ibùgbé rẹ, gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn, kí o sì mú ọ̀ràn wọn dúró, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọn, tí wọn ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.

2 Chronicles 6:39 · Bíbélì Mímọ́

← PreviousRead 2 Chronicles 6Next →

2 Chronicles 6:39 in other translations

KJV King James Version

Then hear thou from the heavens, even from thy dwelling place, their prayer and their supplications, and maintain their cause, and forgive thy people which have sinned against thee.

BSB Berean Standard Bible

then may You hear from heaven, Your dwelling place, their prayer and petition, and may You uphold their cause. May You forgive Your people who sinned against You.

WEB World English Bible

then hear from heaven, even from your dwelling place, their prayer and their petitions, and maintain their cause, and forgive your people who have sinned against you.

Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.

In context

36 “Nígbà tí wọ́n bá sì dẹ́ṣẹ̀ sí ọ—nítorí kò sí ènìyàn kan tí kì í dẹ́ṣẹ̀—bí o bá sì bínú sí wọn tí o bá sì fi wọ́n fún àwọn ọ̀tá, tí wọ́n kó wọn ní ìgbèkùn sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré tàbí nítòsí,

37 ṣùgbọ́n, nígbà tí wọ́n bá sì yí ọkàn wọn padà ní ilẹ̀ tí wọ́n ti mú wọn ní ìgbèkùn, tí wọ́n sì ronúpìwàdà tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn, wọn ó sì wí pé, ‘Àwa ti dẹ́ṣẹ̀, àwa sì ti ṣe ohun tí kò dára, a sì ti ṣe búburú’;

38 tí wọn bá sì yípadà sí ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn àti ẹ̀mí ní ilẹ̀ ìgbèkùn wọn níbi tí wọ́n ti mú wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà wọn, kojú si ìlú tí ìwọ ti yàn àti lórí ilé Olúwa tí mo ti kọ́ fún orúkọ rẹ;

39 nígbà náà, láti ọ̀run, ibi ibùgbé rẹ, gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn, kí o sì mú ọ̀ràn wọn dúró, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọn, tí wọn ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.

40 “Nísinsin yìí, Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ojú rẹ kí ó ṣí kí o sì tẹ́ etí rẹ sílẹ̀ fún àdúrà sí ibí yìí.

41 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí dìde, Olúwa Ọlọ́run mi, sí ibi ìsinmi rẹ, ìwọ àti àpótí ẹ̀rí agbára rẹ. Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, Olúwa Ọlọ́run mi, kí o wọ̀ wọ́n láṣọ pẹ̀lú ìgbàlà, jẹ́ kí àwọn àyànfẹ́ kí inú wọn kí ó dùn nínú ilé rẹ.

42 Olúwa Ọlọ́run mi, má ṣe kọ̀ ẹni àmì òróró rẹ. Rántí ìfẹ́ ńlá tí ó ṣe ìlérí fún Dafidi ìránṣẹ́ rẹ.”

Read 2 Chronicles 6 in the app The whole chapter

Search the Scriptures

Choose a translation

KJVBSBWEBNHEBASVYLTDBYWBTBBEEBRGNVDRALUTCANRIVLSGRVABPMYORIGBSWATGLIRV