The Bible › Bíbélì Mímọ́ › 2 Chronicles 13
Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé Olúwa Ọlọ́run Israẹli ti fún Dafidi àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ ni oyè ọba títí láé nípasẹ̀ májẹ̀mú iyọ̀?
2 Chronicles 13:5 · Bíbélì Mímọ́
← PreviousRead 2 Chronicles 13Next →
Ought ye not to know that the LORD God of Israel gave the kingdom over Israel to David for ever, even to him and to his sons by a covenant of salt?
Do you not know that the LORD, the God of Israel, has given the kingship of Israel to David and his descendants forever by a covenant of salt ?
Ought you not to know that the LORD, the God of Israel, gave the kingdom over Israel to David forever, even to him and to his sons by a covenant of salt?
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
2 Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Mikaiah, ọmọbìnrin Urieli ti Gibeah. Ogun wà láàrín Abijah àti Jeroboamu.
3 Abijah lọ sí ojú ogun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun ogún ọ̀kẹ́ (400,000) ọkùnrin alágbára, Jeroboamu kó ogun jọ pẹ̀lú ogójì ọ̀kẹ́ (800,000) ọ̀wọ́ ogun tí ó lágbára.
4 Abijah dúró lórí òkè Semaraimu ní òkè orílẹ̀-èdè Efraimu, ó sì wí pé, Jeroboamu àti gbogbo Israẹli, ẹ gbọ́ mi!
5 Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé Olúwa Ọlọ́run Israẹli ti fún Dafidi àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ ni oyè ọba títí láé nípasẹ̀ májẹ̀mú iyọ̀?
6 Síbẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, oníṣẹ́ Solomoni ọmọ Dafidi, ṣọ̀tẹ̀ sí ọ̀gá rẹ̀.
7 Àwọn ènìyàn lásán sì kó ara wọn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, àwọn ọmọ ẹni búburú, wọ́n sì kẹ̀yìn sí Rehoboamu ọmọ Solomoni ní ìgbà tí ó sì kéré tí kò lè pinnu fúnra rẹ̀, tí kò lágbára tó láti takò wọ́n.
8 “Nísinsin yìí, ìwọ ṣètò láti kọ́ ìjọba Olúwa, tí ó wà lọ́wọ́ àwọn àtẹ̀lé Dafidi. Ìwọ jẹ́ ọmọ-ogun tí ó gbilẹ̀, ìwọ sì ní pẹ̀lú rẹ ẹgbọrọ màlúù wúrà ti Jeroboamu dà láti fi ṣe Ọlọ́run yín.
Read 2 Chronicles 13 in the app The whole chapter