The Bible › Bíbélì Mímọ́ › 1 Chronicles 4
wọ́n sì lọ sí ojú ọ̀nà Gedori. Lọ títí dé ìlà-oòrùn àfonífojì láti wá koríko fún àwọn agbo ẹran wọn.
1 Chronicles 4:39 · Bíbélì Mímọ́
← PreviousRead 1 Chronicles 4Next →
And they went to the entrance of Gedor, even unto the east side of the valley, to seek pasture for their flocks.
and they journeyed to the entrance of Gedor, to the east side of the valley, in search of pasture for their flocks.
They went to the entrance of Gedor, even to the east side of the valley, to seek pasture for their flocks.
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
36 àti pẹ̀lú Elioenai, Jaakoba, Jeṣohaiah, Asaiah, Adieli, Jesimieli, Benaiah,
37 àti Sisa ọmọ Ṣifi ọmọ Alloni, ọmọ Jedaiah, ọmọ Ṣimri ọmọ Ṣemaiah.
38 Àwọn ọkùnrin tí a dárúkọ lókè yìí àwọn ni ìjòyè ìdílé wọn. Àwọn ìdílé sì pọ̀ sí i gidigidi,
39 wọ́n sì lọ sí ojú ọ̀nà Gedori. Lọ títí dé ìlà-oòrùn àfonífojì láti wá koríko fún àwọn agbo ẹran wọn.
40 Wọ́n sì rí koríko tútù tí ó dára ilẹ̀ náà gbòòrò ó sì ní àlàáfíà ó sì gbé jẹ́. Àwọn ọmọ Hamu ni ó ti ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.
41 Àwọn ọkùnrin tí a kọ orúkọ rẹ̀ sókè, dé ní ọjọ́ Hesekiah ọba Juda. Wọ́n sì kọlu àwọn ará Hamu ní àgọ́ wọn àti pẹ̀lú àwọn ará Mehuni tí a rí níbẹ̀ tí ó sì pa wọ́n run pátápátá títí di òní yìí. Wọ́n sì ń gbé ní ipò wọn, nítorí pé koríko ń bẹ níbẹ̀ fún agbo ẹran wọn.
42 Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) nínú àwọn ará Simeoni, lábẹ́ ìdarí pẹ̀lú Pelatiah, Neariah, Refaiah àti Usieli, àwọn ọmọ Iṣi, gbógun sí àwọn òkè ìlú ti Seiri.
Read 1 Chronicles 4 in the app The whole chapter