The Bible › Bíbélì Mímọ́ › 1 Chronicles 21
Nígbà náà Dafidi sọ fún Ọlọ́run pé, èmi ti dẹ́ṣẹ̀ gidigidi nípa ṣíṣe èyí. Nísinsin yìí, èmi bẹ̀ ọ́, mú ìjẹ̀bi àwọn ìránṣẹ́ rẹ kúrò. Èmi ti hùwà aṣiwèrè gidigidi.
1 Chronicles 21:8 · Bíbélì Mímọ́
← PreviousRead 1 Chronicles 21Next →
And David said unto God, I have sinned greatly, because I have done this thing: but now, I beseech thee, do away the iniquity of thy servant; for I have done very foolishly.
Then David said to God, “I have sinned greatly because I have done this thing. Now I beg You to take away the iniquity of Your servant, for I have acted very foolishly.”
David said to God, “I have sinned greatly, in that I have done this thing. But now put away, I beg you, the iniquity of your servant, for I have done very foolishly.”
Every translation above is public domain and free to share. Other versions — NIV · ESV · NKJV · NLT · NASB · CSB · AMP — are copyrighted and open on their publishers’ partner site.
5 Joabu sì fi àpapọ̀ iye àwọn ènìyàn náà fún Dafidi. Ní gbogbo Israẹli, ó sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún àti ọ̀kẹ́ márùn-ún ènìyàn (1,100,000) tí ń kọ́ idà, Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́tàlélógún lé ẹgbàárùn-ún (470,000) ọkùnrin tí ń kọ́ idà.
6 Ṣùgbọ́n Joabu kó àwọn Lefi àti Benjamini mọ́ iye wọn, nítorí àṣẹ ọba jẹ́ ìríra fún un.
7 Àṣẹ yìí pẹ̀lú sì jẹ́ búburú lójú Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ó sì díyàjẹ Israẹli.
8 Nígbà náà Dafidi sọ fún Ọlọ́run pé, èmi ti dẹ́ṣẹ̀ gidigidi nípa ṣíṣe èyí. Nísinsin yìí, èmi bẹ̀ ọ́, mú ìjẹ̀bi àwọn ìránṣẹ́ rẹ kúrò. Èmi ti hùwà aṣiwèrè gidigidi.
9 Olúwa sì fi fún Gadi, aríran Dafidi pé.
10 “Lọ kí o sì wí fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, èmi fi nǹkan mẹ́ta lọ̀ ọ́; yan ọ̀kan nínú wọn, kí èmi ó sì ṣe é sí ọ.’ ”
11 Bẹ́ẹ̀ ni Gadi tọ Dafidi wá, ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Yan fún ara rẹ.
Read 1 Chronicles 21 in the app The whole chapter